Fisayo Ajisola
Fisayo Ajisola | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Oluwafisayo Ajibola Ajisola Ipinle Eko, Naijiria |
Iṣẹ́ | Osere, Akọrin, Awoṣe |
Ìgbà iṣẹ́ | 2011 – lọwọlọwọ |
Website | jef.org.ng |
Fisayo Ajisola , ti a tun mọ ni Freezon, [1] jẹ oṣere tẹlifisiọnu ati oṣere fiimu, awoṣe ati akọrin. Oruko re tan daada julọ fun ipa rẹ ninu ere tẹlifisiọnu Naijiria kan Jenifa's Diary, pelu ajosepo Funke Akindele. Oruko re tun tan fun awọn ipa rẹ ninu awon ere tẹlifisiọnu; This Life, Nectar, Shadows, Burning Spear, Circle of Interest ati The Story of Us .[2] O jẹ akeko gboye ni Biokemisitiri lati Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB), Ipinle Ogun.[1]
Igbesi aye ibere[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Fisayo ni a bi ni Eko, Naijiria ati pe o jẹ ọmọ ikẹhin ninu awọn ọmọ mẹrin ti awọn obi rẹ. O je elede Yoruba, o si wa lati Ayedun ni ipinlẹ Ekiti, guusu iwọ-oorun Naijiria.[3] Ajisola bẹrẹ si kopa ninu awọn ere ati awọn eré onishoki, lakoko ti o wa ni ile-iwe eleko mewa Federal Government College (FGC) Odogbolu, Ipinle Ogun. Ni oṣu keje ọdun 2010, o forukọsilẹ ni Ile-iwe PEFTI to wa fun ere itage ti Wale Adenuga da sile ni Ilu Eko, Naijiria, nibi ti o ti kẹkọ eré itage.[3] Iṣe akiyesi akọkọ rẹ, waye n bi Nnena and Friends Show, ni Oṣu Kẹwa Ọjọ 1, Ọdun 2010, nibiti o ti se agbekalẹ iṣẹ orin kan.[3] Lakoko ti o wa ni Ile-ẹkọ giga, Ajisola ṣeto ipilẹ kan ti kii ṣe ti ijọba (NGO) Jewel Empowerment Foundation, pẹlu emi iṣẹ lati mu wahala ti awujọ duro nipa sise ifiagbara fun awon ọdọ ati idamọran awọn ọmọde.[4]
Ise ise[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Fisayo bẹrẹ iṣẹ oṣere rẹ ni ọdun 2011, pẹlu awọn ipa ninu awon ere tẹlifisiọnu Naijiria bii “Tinsel”, “Spear Burning” ati “Circle of interest”. O gba isinmi kuro nibi ere ṣiṣe ni Oṣu Kẹsan, ọdun 2011 nigbati o ri igbawole si Ile-ẹkọ giga. Ajisola ṣe ifilọlẹ iṣẹ ṣiṣe fiimu re ni ọdun 2016[1] pẹlu sise fiimu Road to Ruin ni ifowosowopo pẹlu ipilẹ rẹ, Jewel Empowerment Foundation (JEF)[3] pẹlu ero lati gba ijọba niyanju lati gbe igbese fun ipese awọn iṣẹ fun awọn ọdọ Naijiria.[5] Oṣere Raphael Niyi Stephen, ti o kopa ninu fiimu naa, ti sọ pe: "Fiimu naa jẹ ọna lati jẹ ki awon eniyan mọ ohun ti n ṣẹlẹ si awọn ọmọde ati lati tun tele ohun ti ijọba n ṣe nipa ikiri oja, lati jẹ ki awọn eniyan mọ pe ikiri oja ko ni n ti o kan fun awon omo wa".[6]
Akojo ere[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Ere telifisonu[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Odun | Akole | Ipa | Agberejade/Aludari | Afikun |
---|---|---|---|---|
2011 | Tinsel | Alajose | Tope Oshin Ogun | ere Telifisonu Mnet |
2011 | Burning Spear | Asiwaju | Akin Akindele | ere Telifisonu |
2011 | Circle of Interest | Alajose | Kalu Anya | ere Telifisonu |
2012 | Shadows | Asiwaju | Tunde Olaoye | ere Telifisonu |
2014 | Nectar | Alajose | Sola Sobowale | ere Telifisonu |
2015 | This Life | Ipa atilẹyin | Wale Adenuga | ere Telifisonu |
2016 | Jenifa's Diary | Alajose | Funke Akindele | ere Telifisonu alawada |
Awọn itọkasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
- ↑ 1.0 1.1 1.2 "Fisayo Ajisola To Consolidate On Acting Career In 2016". Leadership. Retrieved 23 September 2016.
- ↑ Amu, P (25 April 2016). "I Like Playing Crazy and Sexy Roles". AM Update. Archived from the original on 18 September 2016. https://web.archive.org/web/20160918042239/http://amupdate.com/2016/04/25/i-like-playing-crazy-and-sexy-roles-fisayo-ajisola/. Retrieved 23 September 2016.
- ↑ 3.0 3.1 3.2 3.3 Ebere, P (25 April 2016). "Meet Fisayo Ajisola a young Humanitarian, intelligent, pretty and excellent Actor...". Nigeria Films. https://www.nigeriafilms.com/movie-news/105-upcoming-celebrities/18879-meet-fisayo-ajisola-a-young-humanitarian-intelligent-pretty-and-excellent-actor. Retrieved 30 September 2016.
- ↑ Ogun, Tade (10 February 2016). "How I cope with male admirers - Fisayo Ajisola". Encomium Magazine. http://encomium.ng/how-i-cope-with-male-admirers-actress-fisayo-ajisola/. Retrieved 30 September 2016.
- ↑ "Fisayo Ajisola out with new movie". New Telegraph. 18 September 2016. Archived from the original on 24 September 2016. Retrieved 23 September 2016.
- ↑ "Nollywood actress, Fisayo, produces first movie ‘Road To Ruin’". Nigerian Tribune. 11 September 2016. http://tribuneonlineng.com/nollywood-actress-fisayo-produces-first-movie-road-ruin/. Retrieved 23 September 2016.